Numbers 21:4-20

Ejò idẹ

4Wọ́n rin ìrìnàjò láti òkè Hori lọ sí ọ̀nà tó lọ sí Òkun Pupa, láti kọjá yípo Edomu. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn bínú ní ojú ọ̀nà; 5wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí Ọlọ́run àti Mose, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti kí a ba le wá kú sí aginjù yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kórìíra oúnjẹ tí kò dára yìí!”

6Nígbà náà ni Olúwa rán ejò olóró sí àárín wọn; wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sì kú. 7Àwọn ènìyàn sì wá sí ọ̀dọ̀ Mose wọn wí pé, “A ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí asọ̀rọ̀-òdì sí Olúwa àti sí ìwọ pẹ̀lú. Gba àdúrà pé kí Olúwa mú ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Nígbà náà ni Mose gbàdúrà fún àwọn ènìyàn.

8 Olúwa sọ fún Mose pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.” 9Nígbà náà ni Mose sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, Bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè.

Ìrìnàjò sí Moabu

10Àwọn ọmọ Israẹli tẹ̀síwájú wọ́n sì péjọ sí Obotu. 11Wọ́n gbéra ní Obotu wọ́n sì pa ibùdó sí Iye-Abarimu, ní aginjù tí ó kọjú sí Moabu ní ìdojúkọ ìlà-oòrùn. 12Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti gbéra wọ́n sì pa ibùdó ní Àfonífojì Seredi. 13Láti ibẹ̀ lọ, wọn ṣí, wọ́n sì dó sí ìhà kejì Arnoni, tí ó wà ní aginjù tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ àwọn ọmọ Amori. Arnoni jẹ́ ààlà fún ilẹ̀ Moabu, láàrín Moabu àti Amori. 14Ìdí nìyìí tí ìwé ogun Olúwa se wí pé:

“…Wahebu ní Sufa, Òkun pupa àti
ní odò Arnoni
15àti ní ìṣàn odò
tí ó darí sí ibùjókòó Ari
tí ó sì fi ara ti ìpínlẹ̀ Moabu.”
16Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ rìn dé Beeri, èyí ni kànga tí Olúwa sọ fún Mose, “Kó àwọn ènìyàn jọ èmi ó sì fún wọn ní omi.”

17Nígbà náà ni Israẹli kọ orin yìí pé:

“Sun jáde, ìwọ kànga!
Ẹ máa kọrin nípa rẹ̀,
18nípa kànga tí àwọn ọmọ-aládé gbẹ́,
nítorí àwọn ọlọ́lá ènìyàn ni ó gbẹ́ ẹ;
tí àwọn ọlọ́lá àwọn ènìyàn sì fi ọ̀pá aládé àti ọ̀pá oyè wọn gbẹ́.”
Nígbà náà wọ́n kúrò láti aginjù lọ sí Mattana,
19láti Mattana lọ sí Nahalieli, láti Nahalieli lọ sí Bamoti, 20àti láti Bamoti lọ sí àfonífojì ní Moabu níbi tí òkè Pisga, tí ó wà ní òkè ilé omi ti kọjú sí aginjù.

Copyright information for YorBMYO